Ife Anthem


 1.   Ilé-ifè ni orí’run ayé
      Ìlú Oòduà baba Yorùbá
      Èdùmàrè tó dá wa sí’fè
      Kó máse ba ’fe jé mó wa l’órí
      K’Olúwa kó maa ràn wá se.

Refrain
       Ifè Oòyè, E jí gìrì
       E jí gìrì, k’e gbé Ifè ga
       Olórí aye ni’fè Oòyè
       K’á múra láti tè s’íwájú
       Òràmfè On’ílé iná
       Oòduà a wèriri jagun
       Òkànlén’írún irúnmolè
       E gbé ’fè lé’kĕ ’sòro gbogbo

2.    Ilé-ifè b’ojúmó ti mó wá
       Ìlú àsà on ìlú èsìn
       Gbogbo Yorùbá e káre ’fè
       Ká lo w’ohun àdáyébá t’ó jo’jú
       Ilé Oòduà Ifè l’ó wà
       Opá Òràn’yàn; Ilé-Ifè ni.
’      Boji Morèmi Ilé-Ifè ni
       Ará, e káre ’fè Oòdáyé.

Refrain
        Ifè Oòyè, E jí gìrì
        E jí gìrì, k’e gbé Ifè ga
        Olórí aye ni’fè Oòyè
        K’á múra láti tè s’íwájú
        Òràmfè On’ílé iná
        Oòduà a wèriri jagun
        Òkànlén’írún irúnmolè
        E gbé ’fè lé’kĕ ’sòro gbogbo

Ie8Y6F on Make A Gif, Animated Gifs